Answers2Prayer
BIBLE
TEACHING SERVICE
FOCUS:
JESUS
IWO
ATI OPIN RE
Bibeli
Kika: Oniwasu
3:1-12; 12:1-7, 13-14

Ese Akosori: Ibasepe nwon gbon, ki oye eyi ki o ye won, nwon iba ro igbehin won! Deut. 32:29
Ifaara: Bi ohunkohun ba ye ko je okan tabi ki o kun okan onigbagba kan, ohun naa ni bawo yoo se pari aye re. Bibeli wipe “Opin nkan san ju ibeere re lo…”. Kosi oludije ti a ma n de ni ade lati ibere sugbon awon ti o ba de opin daradara. A dupe lowo Olorun pe o ti jowo aye re fun Jesu Oluwa sugbon ma ti maa yo nitori opolopo eniyan bere daradara ju tire lo sugbon opin won buru ju ti awon alaigbagbo lo. Ti iwo ko ba ti bere pelu Oluwa a je wipe o nilo ki o tun ipinnu re se fun Olorun ki o si se akiyesi wipe Bibeli wipe… nisinsinyi ni akoko itewogba, kiyesi, nisinsinyi ni ojo igbala – 2 Kor. 6:2. Ki a to tesiwaju o nilo lati gbe ibeere naa yewo, Bawo ni o o se pari aye re? A gba Olorun gbo pe bi esu ba tile ti pinnu opin buburu fun o; nigbati eko yi ba pari o o le yi pada ki o si wa lara awon ti yoo pari aye won
daradara. Amin!
-
Apeere ipari buburu
Opolopo awon eniyan ni ko bere daradara bee si ni won ko pari daradara ani ninu Bibeli pelu. A ko won sile fun wa fun ero wa. Ni idakeji awon kan bere daradara sugbon won ko pari aye won daradara. Nitooto opin won ko wuni. Won da ibinuje sile ani ni orun papaa nitori orun n sokun lori olododo ti o di alaisododo. A o gbe yewo die ninu ogooro irufe awon wonyi ninu Oro
Olorun.
-
Kaini: Gen. 4:1-15. Bawo ni Kaini se bere? Opin re n ko? Nibo ni wahala re wa? E jiroro lori eleyi
daradara.
-
Reubeni: Gen. 29:31-32; 35:22; 49:1-4. Kinni o fa ti a fi fi Reubeni re? Bawo ni a se le pekun tabi diwo iru iyen loni? Fun awon ti o ti se; se ona abayo wa? Ejiroro eleyi pelu ohun ti Jesu se lori
agbelebu.
-
Oba Saulu:
1 Sam. 10:1,9,21-25; 13:11-14l; 15:18:25. Se awari lati inu 1 Sam. 9-12 igbe aye rere ti oba Saulu. Bawo ni o se si iwa wu? Kinni a le ko lati inu aye re?
-
Anania ati Safira: Ise 4:34 - 5:11
Toka si ese tabi awon ese lokolaya yi. Bawo ni won se pari aye won? Ohun ti won yo sile nko, kinni o sele
sii?
Dire ninu awon apeere pupo ti a le se awari re ninu Bibeli ni wonyi. O nilo ki o ye aye re wo, ki o si rii bi ese ba ba ni enu ona re, ki o si gbadura fun aanu re loni ki o to pe
ju.
-
Apeere ipari rere
Bi o tile je wipe opolopo eniyan pari aye won ni ona ti o buru sibe a ni opolopo awon eniyan miran nipa ore-ofe Olorun ti won ni ipari rere laika igba ti won bere si ni gbe igbe-aye rere won:
-
Enoku: Gen. 5:18-24. Okunrin yii ni o bere rinrin re pelu Oluwa ni igba ti o pe omo Orundini Adorun odun (65), ti o si wa ni ibarin deedee pelu Oluwa fun Odunrun odun (300) laisimi. Bawo ni a se le ni iru eri
bayi? Ejiroro.
-
Josefu: Gen. 30:22-34; 37:1-28; 39:1-20; 41:37-46.
o tesiwaju daradara, ti o si pari daradara (Gen. 50:22-26). Opolopo nkan ni a le so nipa Josefu. O je olododo ni gbogbo ojo aye re ti o gbe ninu aye yii. Bawo ni Josefu se se bori awon idanwo re? Bawon ni awa naa se le se bori ni aye idanwo yii? Ejiroro
-
Danieli: Dan. 1:8; 6:1-3, 21-23; 12:8-13.
Eleyi ni okunrin miran ti aye re bere daradara pelu ipinnu lati gbe fun Olorun ni ile ajeji Babiloni. A a so fun pe ki o lo sinmi ni titi di igba opin ohun gbogbo. Ore beere lowo ara re lekan si: bawo ni o o se pari aye re? Se o o sinmi ni tabi o o bere si ni se laala ni ni ayeraye? Ye aye re
wo.
-
Paulu: Ise 9:1-8; Gal. 1:11-16; 2 Tim. 4:7-8.
Paulu ba Oluwa pade nigbati o n se inunibini si ijo ati pe lati igba naa, oun tesiwaju, o si n sise fun Olorun titi o fi so wipe, oun ti ja ija rere igbagbo ati pe oun ti pa igbagbo mo. Se oun pa igbagbo mo? Bawo ni o se n ja ija naa?
-
Bi a se le pari daradara:
Ibere ti o ye ki o kun okan wa lati inu eko yi nipe bawo ni a se le pari aye wa daradara. Laarin opo ti a le se, a nilo lati yewo ki a si ko sile awon ona ti ko dara ti o mu ki awon eniyan apa kinni eko wa pari aye won ni ona ti ko dara, ki awa keko ki asi lepa awon ona ti awon eniyan ti apa keji rin nigba ti won wa lori ile aye, ki a si keko lodo won ki a bale tele awon igbese daradara won. Ranti wipe awon eniyan wonyi ni a mo si Iwo Mimo (Matt. 5:8; Heb. 12:14), keko ki o si pa oro Olorun mo (Joshua 1:8; 2 Tim. 2:15; 3:14-17), gbigbadura si Olorun fun ore-ofe ati iranlowo ti a nilo (Dan. 6:10-11; Ps. 55:16-17; Marku 13:33). Igboran si gbogbo ase Olorun ti a fi fun wa je ohun miran ti o ran won lowo ti yoo si ran wa lowo (Joh. 13:17; 15:14)
Opolopo nkan ni o si tun wa ti won sakiye si, ti awa naa gbodo se akiyesi . Edaruko won ki e si jiroro lori won.
Ipari:
Bi a se n pari eko yi, iwo ati emi nilo lati gbadura ki a si gba ore-ofe lati odo Olorun nitori laika ohun ti an se, opin wa ni o se pataki julo. Ti a ba pari daradara, a ni ere, ti enikeni ko ba ni se bee, yoo ni gbogbo ayeraye lati kabamo. Ranti oloro (Luku 16:19-31). Eje ki a gba adura.

Part of this
series
1 2
3 4
5 6
7 8