For those who:
- Needs encouragement
- Have prayer requests
- Desire to get closer to God.
- Desire for prayer association for your ministry

lighthouse (Peggy's Cove, east coast Canada).
privacy Policy
Ipe Olugbala…. The Saviour’s Call — Yoruba

[Français] | [English] | [Español] | [Yoruba] | [Deutsch]
 [ខ្មែរ។] | [தமிழ்] | [বাংলা] | [Italiano] | [తెలుగు]

Kiyesii, nisisiyini akoko itewogba; 
kiyesii, nisisiyi ni ojo IGBALA 
2 kor.6:2

I pe si Igbala:

Ogbon ti aye n fe ki a gbagbo pe gbogbo esin ti o wa ninuaye je nkan kan naa, pe gbogbo ona ni o losi orun, laika ohun tabi eni ti a gbagbo ninu re. Sugbon se eleyi je otito bii?

Jesu wi pe, Emi li ona, ati otito, ati iye: ko si eni ti o le wa sodo Baba, bikose nipase mi. Johannu 14:6

Ise 4:12 wipe ko si igbala lodo elomiran : nitori ko si oruko miran labe orun ti a fifunni ninu eniyan; nipa eyiti a le fi gba wa la.

Loni eyin ore mi, mo gbodo so oju abe niko. Ti oko ba ni Jesu ninu okan re, a ko le gba o la! Laisi Jesu ko si igbala. O pari. Mo toro gafara! Sugbon enikan gbodo le feran re labe wipe a le so fun o, ati pe loni, mo jowo ara mi lati so otito yi fun o.

Sugbon, o wipe Emi ti je kristiani tele! Idile kristiani ni, mo ti dagba. Awa ki se elesin Budha, Musulumi, Juu tabi ti Hindu, a si ma n’ lo soosi ni akoko Ajinde ati keresimesi, nitori naa kristiani ni wa!


Se o mo wipe Bibeli ko so nibi kankan! pe o le de orun tabi gba iye ayeraye nipa pipe ara re ni kristiani?

O dara o dahun wipe, sugbon ile-iwe ti awon kristiani da sile nimo lo. Mo lo si kilase katikisun {tabi ile eko ojo isinmi ti satide tabi ti Sunday} ni gbogbo ojo aye mi.mo ma n wo agbelebu {tabi kristofa mimo} si orun mi!

Eleyi dara, sugbon se o mo pe Bibeli ko so wipe o le de orun tabi ni iye aini pekun nipa lilo si soosi, katikisi, ile-eko ojo isinmi ti satide tabi ti Sunday taabi wiwo agbelebu tabi kristofa mimo si orun re?

O daa… mo ma n ka Bibeli, mosi ma n gbadura lojojumo! Inu mi dun wipe o n se bee!

Ati wipe nitori ti o n se eyi, o timo wipe Bibeli ko so wipe o le de orun ati ki o ni iye ayeraye nipa adura ati eko Bibeli nikan!


O dara. Sugbon mo feran Olorun. Eyi ba mi leru. Sugbon n je o ma pe awon Onisunmoni mokandinlogun ti won wa oko ofurufu kolu ile itaja Agbaye ati ti ile ijoba Pentagon ni ojo kokanla osu kesan, odun 2001, naa so wipe awon na feran Olorun?

Nje o mo wipe Bibeli ko so ohunkohun nipa dide orun ati gbigba iye ayeraye. Nipa ife re fun Olorun nikan?

Sugbon enikan so fun mi nigba kan pe ti mo ba gbagbo pe Jesu Kristi ni omo Olorun, mo le lo si orun, ki nsi ni iye ayeraye.

Je ki n tun so oju-abe niko ? Bibeli wipe awon emi esu papaa gbagbo pe Jesu kristi ni omo Olorun {Jakobu 2:19}, ati wipe satani papaa gbagbo pe Jesu ni omo olorun! Bibeli wipe Jesu ti pese adagun ina ayeraye fun esu ati awon angeli re {matt.25:41}! Igbagbo won ninu Jesu o daju ko le mu iye ayeraye wa fun won l’orun!

Sugbon mo ti pa gbogbo o fin mewewa mo ni gbogbo ojo aye mi!

Eleyi lagbara! Sugbon se o mo wipe Bibeli ko wipe pipa ofin mewa mo yoo mu o gba iye ayeraye? Eyin ore mi, ni kukuru ko si ninu iwe na!

Eje ki a gbe itan Nikodemu wo ni kiakia. Nikodemu je farisi eni ti npo ofin mo gidigidi. O ko Bibeli sori, o n koo lorin, o si n koni ni oro olorun ni gbogbo ojo isinmi. Eniyan a tiro wipe nigbati Nikodemu wa si odo Jesu, pe Oluwa yoo yin, ki o si wipe o kare Nikodemu! Orun n duro de o!

Sugbon eleyi ko ni Oluwa so fun Nikodemu rara. Dipo eyi o so fun Nikodemu wipe ayafi ti a ba bi nupa omi ati imi, oun ko le wo inu ijoba Olorun.

O so fun Nikodemu, O GBODO DI ATUNBI {Joh. 3:3}. Kinni eyi tumo si fun o ? o tumo si pe o gbodo di atunbi lati losi orun ati lati ni iye ayeraye!

Ni bayi kinni o tumo si lati di atunbi?

O tumo si wipe o gbodo fun Jesu ni gbogbo okan re ati gbogbo aye re. Bi o ti rorun to niyen! Ti o ko ba ti se bee, a ko ti gba o la.{lekan si mo toro aforiji sugbon enikan gbodo feran re tobe lati so fun o}

Lati Genesisi 1: titi de awon aworan ti o wa lehin Bibeli, Oro Olorun ko yi pada! O gbodo fun olorun ni gbogbo okan re ati gbogbo aye re. Eleyi tumo si wipe Jesu gbodo je Oluwa aye re. O tumo si wipe iwo yoo fi se Oga re! Ti o ko batii fi se oga lori aye re, a je wipe o ko ti di eni igbala. Bi o se ri niyen.

Sugbon mo gba adura igbala yen ni ibi isin itagbangba Billy Graham {tabi isin ikore ita gbangba kan}! Mo dahun si ipe si ifi aye eni fun Jesu ni soosi ni akoko kan!

Eyi dara pupo! Sugbon se o ngbe aye ni ibamu pelu adura naa?

Nje o mo wipe Bibeli ko so nibi kankan pe gbigba adura kan yoo mu o do orun?

O daju, adura naa se pataki, sugbon se o fun un ni gbogbo okan re ati gbogbo aye re nigba ti o gba adura naa? Nje o fi se oga aye re? Tabi adojutofo ina kan ni o fun o ni igbekele lati gbe igbe aye re bi o ti wu o laisi eru lilo si orun apadi?

Se ki n so ohun kan fun o? Kii sise ba yen. Ibasepo patapata pelu Olorun ni tabi ki a ma se rara. Yala ki o fun gbogbo okan ati aye re, fun un ati ki o fi se oga lori aye re, tabi ki o ma di eni igbala! {Ati wipe enikan gbodo feran re to lati so otito fun o}

Eyin ore mi, akoko yi ni fun o lati ye ara re wo! Oni ni ojo igbala re. Laipe n o fun o ni anfani lati wa ni ibare pelu olorun, lati fi gbogbo okan re ati gbogbo aye re, ati ki o gba idaniloju iye ayeraye ni orun

Nje tanio ye ki o dahun si ipe yii?

Je ki n dahun nipa bibere awon ibere die:

Nje o ti fi igba kankan fun Jesu ni gbogbo okan re ati gbogbo aye re? Bi beeko, a je wipe oni ni ojo igbala re!

Nje o ti fi igba kanfi Jesu se oga aye re? Bi beeko, a je wipe oni ni ojo igbala re!

Nje o ti ngbe aye re fun ara re, kii sefun Jesu? Bi o ba ri bee a je wipe oni ni ojo igbala re!

Nje o ti n sa kuro lodo olorun dipo sisa lo sodo Olorun? Bi o ba ri bee a je wipe oni ni ojo igbala re!

Se ori ni oti ni Jesu dipo okan re? Ti o ba ri bee a je wipe oni ni ojo igbala re!

Ti okankan ninu awon ohun ti a ko yi ba se apejuwe re, N o fe lati gba adura kan pelu re.

Ti ko ba da o loju pe eyi se apejuwe. Rii daju!

Ti o n ba nroo pe boya iwo ni mo nba soro. Iwoni oni ni ojo igbala re!

Ti o ba ti se tan lati gba Jesu Kristi nisinsinyi, gegebi Oluwa ati olugbala re, oga re, lati fi gbogbo okan re ati gbogbo aye re fun un nisinsinyi, jowo so wipe emi niyen! E sese se apejuwe mi ni, ati pe mo Setan lati ba Jesu lo!

Halleluyah!

Ti o ba ti je ipe yii, jowo ba wa soro, lo ona ti o wa ni isale

Jowo tele ati bawa soro nisinsinyi…… 
N o dari re ninu adura igbala.

[Video Version] | [Français] | [English] |[Español] | [Yoruba] | [Duetsch] | [ខ្មែរ។] | [தமிழ்]  | [বাংলা] | [Italiano] | [తెలుగు